40 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ lẹ́yìn tí Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ jẹ́ kó lọ ní òmìnira láti Rámà.+ Ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wà lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tó mú un dé ibẹ̀, ó sì wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn láti Jerúsálẹ́mù àti Júdà, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń kó lọ sí Bábílónì.