36 Jèhófà máa lé ìwọ àti ọba tí o bá fi jẹ lórí ara rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀,+ o sì máa sin àwọn ọlọ́run míì níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta+ ṣe.
64 “Jèhófà máa tú ọ ká sáàárín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti ìkángun kan ayé dé ìkángun kejì ayé,+ o sì máa ní láti sin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀.+
27 Jèhófà sọ pé: “Màá mú Júdà kúrò níwájú mi,+ bí mo ṣe mú Ísírẹ́lì kúrò;+ màá kọ Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, ìlú tí mo yàn àti ilé tí mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Orúkọ mi yóò máa wà níbẹ̀.’”+