-
Jeremáyà 41:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
41 Ní oṣù keje, Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà ọmọ Élíṣámà, tó wá láti ìdílé ọba,* tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá míì sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ní Mísípà.+ Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Mísípà, 2 Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde, wọ́n sì fi idà pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pa ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà.
-