17 Màá bínú sí wọn gidigidi nígbà yẹn,+ màá pa wọ́n tì,+ màá sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn+ títí wọ́n á fi pa run. Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti wàhálà bá wá dé bá wọn,+ wọ́n á sọ pé, ‘Ṣebí torí Ọlọ́run wa ò sí láàárín wa ni àjálù yìí ṣe dé bá wa?’+
2 Nítorí náà, ó lọ bá Ásà, ó sì sọ fún un pé: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà á máa wà pẹ̀lú yín tí ẹ ò bá ti fi í sílẹ̀;+ tí ẹ bá sì wá a, á jẹ́ kí ẹ rí òun,+ àmọ́ tí ẹ bá fi í sílẹ̀, á fi yín sílẹ̀.+