18 Níkẹyìn, Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sínú ọgbà ilé rẹ̀, nínú ọgbà Úúsà;+ Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
19 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Méṣúlémétì ọmọ Hárúsì láti Jótíbà.