-
2 Àwọn Ọba 12:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Wọ́n á kó owó tí wọ́n kà náà fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn, ní tiwọn á wá san án fún àwọn oníṣẹ́ igi àti àwọn kọ́lékọ́lé tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Jèhófà,+ 12 títí kan àwọn mọlémọlé àti àwọn agbẹ́kùúta. Wọ́n tún ra ẹ̀là gẹdú àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé Jèhófà, wọ́n sì ná owó náà sórí àwọn àtúnṣe míì tó jẹ mọ́ ilé náà.
-