ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 22:14-20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Torí náà, àlùfáà Hilikáyà, Áhíkámù, Ákíbórì, Ṣáfánì àti Ásáyà lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin+ tó ń jẹ́ Húlídà. Òun ni ìyàwó Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háhásì, ẹni tó ń bójú tó ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Ó ń gbé ní Apá Kejì Jerúsálẹ́mù; wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+ 15 Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ sọ fún ọkùnrin tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 16 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, gbogbo ohun tó wà nínú ìwé tí ọba Júdà kà ni màá ṣe.+ 17 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì+ láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa bẹ̀rẹ̀ sí í jó bí iná lórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+ 18 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, 19 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́* tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀+ níwájú Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ pé màá ṣe sí ibí yìí àti sí àwọn tó ń gbé ibẹ̀, pé wọ́n á di ohun àríbẹ̀rù àti ẹni ègún, tí o sì fa aṣọ rẹ ya,+ tí ò ń sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ, ni Jèhófà wí. 20 Ìdí nìyẹn tí màá fi kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ,* a ó tẹ́ ọ sínú sàréè rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ ò ní rí gbogbo àjálù tí màá mú bá ibí yìí.’”’” Lẹ́yìn náà, wọ́n mú èsì náà wá fún ọba.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́