ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 26:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+

  • Diutarónómì 28:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+

  • Diutarónómì 30:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 “Àmọ́ tí ọkàn yín bá yí pa dà,+ tí ẹ ò fetí sílẹ̀, tí ẹ sì jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ wá ń forí balẹ̀ fún wọn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,+ 18 mò ń sọ fún yín lónìí pé ó dájú pé ẹ máa ṣègbé.+ Ẹ̀mí yín ò sì ní gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.

  • Dáníẹ́lì 9:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Gbogbo Ísírẹ́lì ti tẹ Òfin rẹ lójú, wọ́n sì ti yà kúrò nínú rẹ̀ torí pé wọn ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, tí o fi da ègún àti ìbúra lé wa lórí, èyí tí wọ́n kọ sínú Òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ torí pé a ti ṣẹ̀ Ẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́