14 Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà.
33 Fáráò Nẹ́kò+ fi í sínú ẹ̀wọ̀n ní Ríbúlà+ nílẹ̀ Hámátì, kó má bàa jọba lórí Jerúsálẹ́mù mọ́, ó wá bu owó ìtanràn lé ilẹ̀ náà, ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti tálẹ́ńtì wúrà kan.+