-
Sáàmù 74:4-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù nínú ibi ìpàdé* rẹ.+
Wọ́n fi àwọn ọ̀págun wọn ṣe àmì síbẹ̀.
5 Wọ́n dà bí àwọn ọkùnrin tó ń fi àáké dá igbó kìjikìji lu.
6 Wọ́n fi àáké àti àwọn ọ̀pá onírin fọ́ àwọn iṣẹ́ ọnà ara rẹ̀.+
7 Wọ́n sọ iná sí ibi mímọ́ rẹ.+
Wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn tí o fi orúkọ rẹ pè di aláìmọ́, wọ́n sì wó o lulẹ̀.
-