-
2 Kíróníkà 7:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Jèhófà wá fara han Sólómọ́nì+ ní òru, ó sì sọ fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ, mo sì ti yan ibí yìí fún ara mi láti jẹ́ ilé ìrúbọ.+ 13 Nígbà tí mo bá sé ọ̀run pa, tí òjò kò sì rọ̀, nígbà tí mo bá pàṣẹ fún àwọn tata láti jẹ ilẹ̀ náà run, tí mo bá sì rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín àwọn èèyàn mi, 14 tí àwọn èèyàn mi tí à ń fi orúkọ mi pè+ sì rẹ ara wọn sílẹ̀,+ tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n wá ojú mi, tí wọ́n sì kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn,+ nígbà náà, màá gbọ́ láti ọ̀run, màá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, màá sì wo ilẹ̀ wọn sàn.+
-