-
1 Àwọn Ọba 8:35, 36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀+ torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+ 36 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà+ tó yẹ kí wọ́n máa rìn; kí o sì rọ̀jò sórí ilẹ̀ rẹ+ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.
-