1Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn onídàájọ́+ ń ṣe àbójútó* ní Ísírẹ́lì, ìyàn mú ní ilẹ̀ náà. Ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀* Móábù.+
25 Torí náà, ìyàn ńlá+ kan mú ní Samáríà, wọ́n sì dó tì í títí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ kan ní ọgọ́rin (80) ẹyọ fàdákà, ìlàrin òṣùwọ̀n káàbù* imí àdàbà sì di ẹyọ fàdákà márùn-ún.