-
1 Àwọn Ọba 12:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa lọ, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta; kí ẹ pa dà wá.” Torí náà, àwọn èèyàn náà lọ.+ 6 Ọba Rèhóbóámù wá fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbà ọkùnrin* tó bá Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó wà láàyè, ó ní: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn yìí?” 7 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Tí o bá sọ ara rẹ di ìránṣẹ́ àwọn èèyàn yìí lónìí, tí o ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, tí o sì fún wọn ní èsì rere, ìwọ ni wọ́n á máa sìn títí lọ.”
-