-
2 Kíróníkà 34:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́,+ 27 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́,* tí o rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run bí o ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi, tí o fa aṣọ rẹ ya, tí o sì sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ,+ ni Jèhófà wí.
-