-
2 Kíróníkà 26:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Bákan náà, Ùsáyà ní àwọn ọmọ ogun tó ti gbára dì fún ogun. Wọ́n máa ń jáde ogun, wọ́n á sì to ara wọn ní àwùjọ-àwùjọ. Jéélì akọ̀wé+ àti Maaseáyà tó jẹ́ aláṣẹ ló kà wọ́n, wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀+ lábẹ́ àṣẹ Hananáyà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. 12 Iye gbogbo àwọn olórí agbo ilé tí wọ́n ń bójú tó àwọn akíkanjú jagunjagun yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600). 13 Ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (307,500) àwọn ológun ló wà lábẹ́ àṣẹ wọn, wọ́n sì ti múra ogun, wọ́n jẹ́ àwùjọ ọmọ ogun tó máa ti ọba lẹ́yìn láti gbógun ti ọ̀tá.+
-