7 Ni ọba Ísírẹ́lì bá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà+ tí a lè ní kó bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà; ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀, nítorí kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi ibi ṣáá.+ Mikáyà ni orúkọ rẹ̀, ọmọ Ímílà ni.” Síbẹ̀, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Kí ọba má sọ bẹ́ẹ̀.”