-
1 Àwọn Ọba 22:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Àmọ́, ọkùnrin kan ṣàdédé ta ọfà rẹ̀,* ó sì ba ọba Ísírẹ́lì láàárín ibi tí ẹ̀wù irin rẹ̀ ti so pọ̀. Torí náà, ọba sọ fún ẹni tó ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Yí pa dà, kí o sì gbé mi jáde kúrò lójú ogun,* nítorí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.”+ 35 Ìjà náà le gan-an jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, kódà wọ́n ní láti gbé ọba nàró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará Síríà jà. Ẹ̀jẹ̀ ọgbẹ́ náà ń dà jáde sínú kẹ̀kẹ́ ogun náà, ó sì kú ní ìrọ̀lẹ́.+
-