5 “Kí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì sì wá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun,+ kí wọ́n sì máa súre ní orúkọ Jèhófà.+ Wọ́n á sọ bí wọ́n á ṣe máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìwà ipá.+
25“Tí àwọn èèyàn bá ń bára wọn fa ọ̀rọ̀, kí wọ́n kó ara wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́,+ wọ́n á sì bá wọn dá ẹjọ́ wọn, wọ́n á dá olódodo láre, wọ́n á sì dá ẹni burúkú lẹ́bi.+