12 Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àti ògo ti wá,+ o sì ń ṣàkóso ohun gbogbo,+ ọwọ́ rẹ ni agbára+ àti títóbi+ wà, ọwọ́ rẹ ló lè sọni di ńlá,+ òun ló sì lè fúnni lágbára.+
35 Kò ka gbogbo àwọn tó ń gbé ayé sí nǹkan kan, ohun tó bá sì wù ú ló ń ṣe láàárín àwọn ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn tó ń gbé ayé. Kò sí ẹni tó lè dá a dúró*+ tàbí kó sọ fún un pé, ‘Kí lo ṣe yìí?’+