-
2 Àwọn Ọba 8:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Níkẹyìn, Jèhórámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì.+ Ahasáyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
25 Ní ọdún kejìlá Jèhórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Ahasáyà ọmọ Jèhórámù ọba Júdà di ọba.+ 26 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ahasáyà nígbà tó jọba, ọdún kan ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ataláyà+ ọmọ ọmọ* Ómírì+ ọba Ísírẹ́lì.
-