-
2 Àwọn Ọba 10:10-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, ẹ mọ̀ dájú pé kò sí ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Jèhófà kéde sórí ilé Áhábù tí kò ní ṣẹ,*+ Jèhófà sì ti ṣe ohun tó gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà sọ.”+ 11 Yàtọ̀ síyẹn, Jéhù pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Jésírẹ́lì, títí kan gbogbo sàràkí ọkùnrin rẹ̀, àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà rẹ̀,+ kò jẹ́ kí èèyàn rẹ̀ kankan ṣẹ́ kù.+
12 Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì forí lé Samáríà. Ilé tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń so àgùntàn mọ́lẹ̀* wà lójú ọ̀nà. 13 Ibẹ̀ ni Jéhù ti bá àwọn arákùnrin Ahasáyà+ ọba Júdà pàdé, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?” Wọ́n sọ pé: “Arákùnrin Ahasáyà ni wá, a fẹ́ lọ béèrè àlàáfíà àwọn ọmọ ọba àti àwọn ọmọ ìyá ọba.”* 14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ mú wọn láàyè!” Torí náà, wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n níbi kòtò omi tó wà ní ilé tí wọ́n ti ń so àgùntàn mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹ́ méjìlélógójì (42). Kò sì jẹ́ kí ìkankan lára wọn ṣẹ́ kù.+
-