-
1 Àwọn Ọba 7:38, 39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Ó ṣe bàsíà bàbà+ mẹ́wàá; ogójì (40) òṣùwọ̀n báàtì ni bàsíà kọ̀ọ̀kan ń gbà. Ìwọ̀n bàsíà kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin.* Kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ní bàsíà kọ̀ọ̀kan lórí. 39 Lẹ́yìn náà, ó gbé kẹ̀kẹ́ ẹrù márùn-ún sí apá ọ̀tún ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ilé náà, ó sì gbé Òkun náà sí apá ọ̀tún ilé náà láàárín gúúsù àti ìlà oòrùn.+
-