-
2 Kíróníkà 15:10-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìjọba Ásà. 11 Lọ́jọ́ yẹn, wọ́n fi ọgọ́rùn-ún méje (700) màlúù àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn rúbọ sí Jèhófà látinú ẹrù ogun tí wọ́n kó dé. 12 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n dá májẹ̀mú pé àwọn á fi gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara*+ wọn wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 13 Wọ́n á pa ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, ọkùnrin tàbí obìnrin.+
-