3 Ibi àbáwọlé*+ tó wà níwájú tẹ́ńpìlì* náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn,* ó sì bá fífẹ̀ ilé náà mu.* Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ló fi yọ síta lára iwájú ilé náà.
11 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ní àwòrán ìkọ́lé+ ti ibi àbáwọlé*+ àti ti àwọn ilé rẹ̀, àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn yàrá orí òrùlé, àwọn yàrá inú àti ti ilé ìbòrí ìpẹ̀tù.*+