7 Kí àlùfáà náà tún fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àwọn ìwo pẹpẹ tùràrí onílọ́fínńdà,+ tó wà níwájú Jèhófà nínú àgọ́ ìpàdé; kó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun,+ tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
18 Kó wá fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn ìwo pẹpẹ+ tó wà níwájú Jèhófà, èyí tó wà nínú àgọ́ ìpàdé; kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun, tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+