-
1 Kíróníkà 28:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé gbogbo ohun tí a fi hàn án nípa ìmísí* nípa àwọn àgbàlá+ ilé Jèhófà, ti gbogbo àwọn yàrá ìjẹun tó yí i ká, ti àwọn ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti ti àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di* mímọ́+ sí; 13 bákan náà, ó sọ fún un nípa àwọn àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì, gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà àti gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà;
-
-
2 Kíróníkà 8:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Síwájú sí i, ó yan àwùjọ àwọn àlùfáà+ sí àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì bàbá rẹ̀ fi lélẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ wọn, láti máa yin+ Ọlọ́run àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú àwọn àlùfáà bí wọ́n ti ń ṣe lójoojúmọ́, ó tún yan àwùjọ àwọn aṣọ́bodè sí ẹnubodè kọ̀ọ̀kan,+ nítorí ohun tí Dáfídì, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ nìyẹn.
-