ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 23:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Àwọn ọmọ Ámúrámù ni Áárónì+ àti Mósè.+ Àmọ́ a ya Áárónì sọ́tọ̀+ láti máa sìn ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ títí lọ, kí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa rú ẹbọ níwájú Jèhófà, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún àwọn èèyàn nígbà gbogbo.+

  • 1 Kíróníkà 23:27-30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáfídì sọ kẹ́yìn pé kí wọ́n ṣe, wọ́n ka iye àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ogún (20) ọdún sókè. 28 Iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Áárónì+ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà, kí wọ́n máa bójú tó àwọn àgbàlá,+ àwọn yàrá ìjẹun, mímú kí gbogbo ohun mímọ́ wà ní mímọ́ àti iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú nínú iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. 29 Wọ́n ń ṣe búrẹ́dì onípele*+ àti ìyẹ̀fun kíkúnná tí wọ́n ń lò fún ọrẹ ọkà, wọ́n tún ń ṣe àwọn búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ+ àti àwọn àkàrà tí wọ́n fi agbada dín, wọ́n ń po ìyẹ̀fun títí á fi rọ́,+ wọ́n sì ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe pọ̀ tó àti bí ó ṣe tóbi tó. 30 Iṣẹ́ wọn ni láti máa dúró ní àràárọ̀  + láti máa dúpẹ́, kí wọ́n sì máa yin Jèhófà, ohun kan náà ni wọ́n sì ń ṣe ní ìrọ̀lẹ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́