ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 30:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀.+ 20 Tí wọ́n bá ń lọ sínú àgọ́ ìpàdé tàbí tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́, láti fi iná sun ọrẹ kó sì rú èéfín sí Jèhófà, kí wọ́n lo omi náà kí wọ́n má bàa kú.

  • Léfítíkù 21:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Kí o sọ ọ́ di mímọ́,+ torí òun ló ń gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ wá. Kó jẹ́ mímọ́ sí ọ, torí èmi Jèhófà, tó ń sọ yín di mímọ́, jẹ́ mímọ́.+

  • Léfítíkù 22:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n kíyè sára pẹ̀lú bí wọ́n á ṣe máa ṣe* ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má sì fi àwọn ohun tí wọ́n ń yà sí mímọ́ fún mi+ sọ orúkọ mímọ́+ mi di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà. 3 Sọ fún wọn pé, ‘Jálẹ̀ àwọn ìran yín, èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ yín tó bá ṣì jẹ́ aláìmọ́, tó wá sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sí mímọ́ fún Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà kúrò níwájú mi.+ Èmi ni Jèhófà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́