10 Asaráyà olórí àlùfáà ilé Sádókù sì sọ fún un pé: “Láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọrẹ wá sínú ilé Jèhófà+ ni àwọn èèyàn náà ti ń jẹ àjẹyó, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ló ṣẹ́ kù, nítorí Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, ohun tó sì ṣẹ́ kù ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ yìí.”+