6 Ẹ́sírà yìí dé láti Bábílónì. Ó jẹ́ adàwékọ* tó mọ Òfin Mósè+ dunjú,* èyí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Gbogbo ohun tó béèrè ni ọba fún un, nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà lára rẹ̀.
2 Torí náà, ní ọjọ́ kìíní oṣù keje,+ àlùfáà Ẹ́sírà mú ìwé Òfin náà wá síwájú àpéjọ*+ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin pẹ̀lú gbogbo àwọn tó lè lóye ohun tí wọ́n bá gbọ́.