3 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ọrẹ àfinásun tí ẹ máa mú wá fún Jèhófà nìyí: kí ẹ máa mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá wá lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ sísun nígbà gbogbo.+ 4 Kí o mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan wá ní àárọ̀, kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́,+