-
Ẹ́sírà 1:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà. 3 Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́, òun ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ilé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù.*
-
-
Ẹ́sírà 6:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “Ní ọdún kìíní Ọba Kírúsì, Ọba Kírúsì pa àṣẹ kan nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù, ó ní:+ ‘Ẹ tún ilé náà kọ́ kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ níbẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ sí àyè rẹ̀; kí gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,+ 4 kí ó ní ipele mẹ́ta òkúta ńlá tí wọ́n yí sí àyè wọn àti ipele kan ẹ̀là gẹdú;+ kí owó tí wọ́n máa fi ṣe é sì wá láti ilé ọba.+
-