31 Àwọn tí Dáfídì yàn pé kí wọ́n máa darí orin ní ilé Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n gbé Àpótí náà síbẹ̀ nìyí.+32 Ojúṣe wọn ni láti máa kọrin ní àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ni àgọ́ ìpàdé títí di ìgbà tí Sólómọ́nì kọ́ ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wọn bí wọ́n ṣe ni kí wọ́n máa ṣe é.+
5 ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) jẹ́ aṣọ́bodè,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) sì ń fi àwọn ohun ìkọrin yin+ Jèhófà, èyí tí Dáfídì sọ nípa wọn pé “mo ṣe wọ́n fún kíkọ orin ìyìn.”
25Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì+ sọ́tọ̀ láti máa fi háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti síńbálì*+ sọ tẹ́lẹ̀. Orúkọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ni,