-
Diutarónómì 28:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
-
-
Diutarónómì 28:33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Àwọn èèyàn tí o kò mọ̀+ ló máa jẹ èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Wọ́n á máa lù ọ́ ní jìbìtì, wọ́n á sì máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ nígbà gbogbo.
-
-
Nehemáyà 9:36, 37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Àwa rèé lónìí, àwa ẹrú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ẹrú lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa pé kí wọ́n máa jẹ èso rẹ̀ àti ohun rere rẹ̀. 37 Ọ̀pọ̀ àwọn ohun rere tí ilẹ̀ náà ń mú jáde jẹ́ ti àwọn ọba tí o fi ṣe olórí wa nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ Wọ́n ń ṣàkóso àwa* àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bó ṣe wù wọ́n, a sì wà nínú wàhálà ńlá.
-