14 Lọ́nà yìí pẹ̀lú, Olúwa pàṣẹ pé kí àwọn tó ń kéde ìhìn rere máa jẹ nípasẹ̀ ìhìn rere.+
15 Àmọ́ mi ò tíì lo ìkankan nínú àwọn ìpèsè yìí.+ Ní tòótọ́, mi ò ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yìí torí kí a lè ṣe wọ́n fún mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n jẹ́ kí ẹnì kan gba ẹ̀tọ́ tí mo ní láti ṣògo!+