-
Ẹ́sírà 4:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Torí pé ààfin ni owó wa ti ń wá,* kò ní dáa ká rí ohun tó máa dènà àǹfààní ọba, ká má sì sọ, ìdí nìyẹn tí a fi kọ̀wé ránṣẹ́, kí ọba lè mọ̀, 15 kí o lè wádìí nínú àkọsílẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ.+ Wàá rí i nínú àkọsílẹ̀ pé ìlú yẹn jẹ́ ìlú ọ̀tẹ̀, ó máa ń pa àwọn ọba àti àwọn ìpínlẹ̀* lára, ó sì ti pẹ́ tí àwọn tó wà nínú rẹ̀ ti máa ń dìtẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pa ìlú náà run.+
-