2Àwọn yìí ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀,* tí wọ́n pa dà lára àwọn tó wà nígbèkùn,+ àwọn tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì,+ àmọ́ tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà tó yá, kálukú pa dà sí ìlú rẹ̀,+
42 Àwọn ọmọ àwọn aṣọ́bodè nìyí:+ àwọn ọmọ Ṣálúmù, àwọn ọmọ Átérì, àwọn ọmọ Tálímónì,+ àwọn ọmọ Ákúbù,+ àwọn ọmọ Hátítà, àwọn ọmọ Ṣóbáì, gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ mọ́kàndínlógóje (139).