25Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ Ó dó tì í, ó mọ òkìtì yí i ká,+
3Ọba Nebukadinésárì ṣe ère wúrà kan, gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.* Ó gbé e kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní ìpínlẹ̀* Bábílónì.