-
Nehemáyà 1:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Lákòókò náà, Hánáánì,+ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin míì láti Júdà wá sọ́dọ̀ mi, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tó ṣẹ́ kù, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú,+ mo tún béèrè nípa Jerúsálẹ́mù. 3 Wọ́n sọ pé: “Àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìpínlẹ̀* Júdà, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú wà nínú ìṣòro ńlá, ìtìjú sì bá wọn.+ Àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀,+ wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀.”+
-