15 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ torí náà, Jèhófà yan ẹnì kan tó máa gbà wọ́n sílẹ̀,+ ìyẹn Éhúdù+ ọmọ Gérà, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ ọkùnrin tó ń lo ọwọ́ òsì.+ Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìṣákọ́lẹ̀ rán an sí Ẹ́gílónì ọba Móábù.