-
2 Kíróníkà 36:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.
-
-
Àìsáyà 42:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ta ló ti mú kí wọ́n kó ohun ìní Jékọ́bù,
Tó sì mú kí wọ́n kó ẹrù Ísírẹ́lì?
Ṣebí Jèhófà ni, Ẹni tí a ṣẹ̀?
-
-
Jeremáyà 40:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ìgbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ mú Jeremáyà, ó sì sọ fún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló sọ pé àjálù yìí máa bá ibí yìí, 3 Jèhófà sì ti mú kó ṣẹlẹ̀ bó ṣe sọ, nítorí pé ẹ̀yin èèyàn yìí ti ṣẹ Jèhófà, ẹ kò sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí yín.+
-