-
Diutarónómì 15:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Ní òpin ọdún méje-méje, kí o máa ṣe ìtúsílẹ̀.+ 2 Bí ìtúsílẹ̀ náà ṣe máa rí nìyí: Kí gbogbo ẹni tí ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ ní gbèsè má ṣe gbà á pa dà. Kó má sọ pé kí ọmọnìkejì rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀ san án pa dà, torí pé a máa kéde rẹ̀ pé ó jẹ́ ìtúsílẹ̀ fún Jèhófà.+ 3 O lè gbà á pa dà lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ kí o fagi lé gbèsè yòówù kí arákùnrin rẹ jẹ ọ́.
-