-
Ẹ́sírà 6:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì + pẹ̀lú àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ fi ìdùnnú ṣe ayẹyẹ ṣíṣí* ilé Ọlọ́run yìí. 17 Ohun tí wọ́n mú wá fún ayẹyẹ ṣíṣí ilé Ọlọ́run yìí ni ọgọ́rùn-ún (100) akọ màlúù, igba (200) àgbò àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì tún mú akọ ewúrẹ́ méjìlá (12) wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì.+
-