-
Nehemáyà 13:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Gbogbo Júdà sì kó ìdá mẹ́wàá+ ọkà àti ti wáìnì tuntun àti ti òróró wá sí àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí.+ 13 Lẹ́yìn náà, mo fi àlùfáà Ṣelemáyà, Sádókù adàwékọ* àti Pedáyà lára àwọn ọmọ Léfì sídìí àbójútó àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, Hánánì ọmọ Sákúrì ọmọ Matanáyà sì ni olùrànlọ́wọ́ wọn, nítorí wọ́n ṣeé fọkàn tán. Iṣẹ́ wọn ni láti pín nǹkan fún àwọn arákùnrin wọn.
-