-
Ẹ́sítà 9:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ìyẹn oṣù Ádárì,*+ nígbà tí ó tó àkókò láti mú ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀ ṣẹ,+ ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá àwọn Júù ti dúró dè láti ṣẹ́gun wọn, ọ̀tọ̀ lohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn Júù ṣẹ́gun àwọn tó kórìíra wọn.+ 2 Àwọn Júù kóra jọ ní àwọn ìlú wọn ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì,+ láti gbéjà ko àwọn tó fẹ́ ṣe wọ́n ní jàǹbá, kò sì sí ẹni tó lè dúró níwájú wọn, nítorí ẹ̀rù wọn ń ba gbogbo àwọn èèyàn.+
-