13 Ẹ́sítà fèsì pé: “Tó bá dáa lójú ọba,+ jẹ́ kí a fún àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* láyè lọ́la láti ṣe ohun tí òfin ti òní sọ;+ sì jẹ́ kí wọ́n gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́ sórí òpó igi.”+
15 Àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* tún kóra jọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì,+ wọ́n sì pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin ní Ṣúṣánì,* àmọ́ wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí.