-
Ẹ́sítà 4:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nígbà tí Módékáì+ gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ṣe,+ ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì da eérú sórí. Ó wá lọ sí àárín ìlú, ó gbé ohùn sókè, ó sì ń sunkún kíkankíkan. 2 Ó ń lọ títí ó fi dé ẹnubodè ọba, àmọ́ kò wọlé, torí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọ̀fọ̀* wọ ẹnubodè ọba. 3 Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ láàárín àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀*+ tí ọ̀rọ̀ ọba àti àṣẹ rẹ̀ ti dé, wọ́n ń gbààwẹ̀,+ wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀ lára wọn sùn sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+
-