-
Ẹ́sítà 4:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Ẹ́sítà fún Módékáì, 13 ó fún Ẹ́sítà lésì pé: “Má rò pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Júù yòókù kò ní kàn ọ́ torí pé o wà nínú agbo ilé ọba. 14 Tí o bá dákẹ́ ní àkókò yìí, àwọn Júù máa rí ìtura àti ìdáǹdè láti ibòmíì,+ ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé bàbá rẹ yóò ṣègbé. Ta ló sì mọ̀ bóyá torí irú àkókò yìí lo fi dé ipò ayaba tí o wà?”+
-