42 Fáráò wá bọ́ òrùka àṣẹ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi sí ọwọ́ Jósẹ́fù. Ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa fún un, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. 43 Ó tún mú kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ kejì tó lọ́lá, ó sì ní kí wọ́n máa kígbe níwájú rẹ̀ pé, “Áfírékì!” Bó ṣe fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì nìyẹn.